27. Ìbẹ̀rù Olúwa jẹ́ oríṣun ìyè,tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìkẹ́kùn ikú.
28. Ènìyàn púpọ̀ ní ìlú jẹ́ ògo Ọba,ṣùgbọ́n láì sí ìjòyè, Ọba á parun.
29. Onísùúrù ènìyàn ní òye tí ó pọ̀,ṣùgbọ́n onínú fùfù ènìyàn máa ń fi ìwà aṣiwèrè hàn.
30. Ọkàn tí ó lálàáfíà fi ìyè mú kí ọjọ́ ayé gùn fún ara,ṣùgbọ́n ìlara mú kí egungun jẹrà.
31. Ẹni tí ó fi ìyà jẹ aláìní ń fi ìkórìíra hànṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó ṣoore fún aláìní bu ọlá fún Ọlọ́run.
32. Nígbà tí ìyọnu bá dé, a fa àwọn búburú lulẹ̀,kódà nínú ikú àwọn olódodo ni ààbò.
33. Ọgbọ́n wà nínú ọkàn olóyekódà láàrin àwọn aláìlóye, ó jẹ́ kí wọn mọ òun.
34. Ododo a máa gbé orílẹ̀ èdè ga,ṣùgbọ́n ìtìjú ni ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ fún àwùjọ káwùjọ.
35. Ọba a máa ní inú dídùn sí ìránṣẹ́ tí ó gbọ́nṣùgbọ́n ìbínú rẹ̀ wá sórí ìránṣẹ́ adójútini.