15. Ìlú mẹ́fà yìí yóò jẹ́ ìlú ìsásí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, fún àlejò àti ẹnikẹ́ni tí ó bá ń gbé láàrin wọn, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ènìyàn ní àìmọ̀ sá lọ ṣíbẹ̀.
16. “ ‘Bí ọkùnrin kan bá fi ohun èlò irin lu ènìyàn tí ó kú, apànìyàn ni, pípa ni a ó pá, apànìyàn náà.
17. Tàbí tí ènìyàn bá mú òkúta tí ó lè pa ènìyàn lọ́wọ́ tí ó sì fi lu ènìyàn, tí ó sì kú, apànìyàn ni, pípa ni a ó pa apànìyàn náà.
18. Tàbí tí ènìyàn bá mú ohun èlò igi ní ọwọ́ ọ rẹ̀ tí ó sì lẹ̀ ẹ́ pa ènìyàn, tí ó sì fi lu ènìyàn, tí ó sì kú, apànìyàn ni; pípa ní a ó pa apànìyàn náà.