Wọ̀nyí ni àwọn olórí agbègbè ìjọba tí wọ́n tẹ̀dó sí Jérúsálẹ́mù (díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ḿpìlì àti àwọn ìran àwọn ìránṣẹ́ Sólómónì ń gbé àwọn ìlúu Júdà, olúkúlùkù ń gbé lórí ilẹ̀ ìníi rẹ̀ ní àwọn ìlú náà.