1. Olúwa sọ fún Mósè pé,
2. “Mú Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, aṣọ wọn, òróró ìtasórí, akọ mààlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àgbò méjì àti apẹ̀rẹ̀ tí a kó àkàrà aláìwú sínú rẹ̀.
3. Kí o sì kó gbogbo ìjọ ènìyàn jọ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.”
4. Mósè sì ṣe bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún un, gbogbo ènìyàn sì péjọ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.
5. Mósè sì sọ fún ìjọ ènìyàn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa ti pa láṣẹ pé kí á ṣe.”
6. Nígbà náà ni Mósè mú Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá ṣíwájú, ó sì fi omi wẹ̀ wọ́n.
7. Ó sì fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ Árónì, ó fi àmùrè dì í, ó wọ̀ ọ́ ní aṣọ ìgúnwà, ó sì tún wọ̀ ọ́ ni aṣọ ìlékè oyè àlùfáà tí ó ní ìgbànú tí a ṣe ọnà dáradára sí.
8. Ó fi ìgbàyà sí àyà rẹ̀, ó sì fi Úrímù àti Júmímù síbi ìgbàyà náà.
9. Ó dé e ní fìlà, ó sì fi àwo wúrà tíí ṣe adé mímọ́ ṣíwájú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.