23. Bí ìjàǹbá bá pani lójijì,yóò rẹ́rín-ín ìdàwọ́ aláìṣẹ̀.
24. Nígbà tí a bá fi ayé lé ọwọ́ ènìyàn búburú;ó sì bo àwọn onídàájọ́ rẹ̀ lójú;bí kò bá rí bẹ́ẹ̀ ǹjẹ́ ta ni?
25. “Ǹjẹ́ nísinsìn yìí ọjọ́ mi yára ju oníṣẹ́ lọ,wọ́n fò lọ, wọn kò rí ayọ̀.
26. Wọ́n kọjá lọ bí ọkọ̀ eésú tí ń ṣúré lọ;bí idì tí ń yára si ohùn ọdẹ.
27. Bí èmi bá wí pé, ‘Èmi ó gbàgbé arò ìbìnújẹ́ mi,èmi ó fi ọkàn lélẹ̀, èmi ó sì rẹ ara mi lẹ́kún.’
28. Ẹ̀rù ìbànújẹ́ mi gbogbo bà mí,èmi mọ̀ pé ìwọ kì yóò mú mi bí aláìṣẹ̀.
29. Bí ó bá ṣe pé ènìyàn búburú ni èmi,ǹjẹ́ kí ni èmi ń ṣe làálàá lásán sí?
30. Bí mo tilẹ̀ fi ọṣẹ ojú dídì wẹ ara mi,tí mo fi omi àrò wẹ ọwọ́ mi mọ́,
31. ṣíbẹ̀ ìwọ ó gbé mi wọ inú ihòọ̀gọ̀dọ̀ aṣọ ara mi yóò sọ mi di ìríra.
32. “Nítorí Òun kì í ṣe ènìyàn bí èmi,tí èmi ó fi dá a lóhùn tí àwa o fi pàdé ní ìdájọ́.
33. Bẹ́ẹ̀ ni kò sí alátúnṣe kan ní agbede-méjì watí ìbá fi ọwọ́ rẹ̀ lé àwa méjèèjì lára.
34. Kí ẹnìkan ṣá à mú ọ̀pá Ọlọ́run kúrò lára mi,kí ìbẹ̀rù rẹ̀ kí ó má sì se dáyà fò mí