26. Ẹ̀yin ṣè bí ẹ ó bá ọ̀rọ̀àti ohùn ẹnu tí ó takú wí tí ó dà bí afẹ́fẹ́.
27. Àní ẹ̀yin ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìní baba,ẹ̀yin sì da iye lé ọ̀rẹ́ yín.
28. “Nítorí náà, kí èyí kí ó tó fún yín.Ẹ má wò mi! Nitorí pé ó hàn gbangba pé:Ní ojú yín ni èmi kì yóò sèké.
29. Èmi ń bẹ̀ yín, ẹ padà, kí ó má sì ṣe jásí ẹ̀ṣẹ̀;àní, ẹ sì tún padà, àre mi ń bẹ nínú ọ̀rọ̀ yìí.