16. Wò o nísinsìnyí, agbára rẹ wà níẹ̀gbẹ́ rẹ, àti ipa rẹ nínú ìṣàn ìkún rẹ.
17. Òun a máa jù ìru rẹ̀ bí i igikédarì; Isan itan rẹ̀ dijọ pọ̀.
18. Egungun rẹ̀ ní ògùsọ̀ idẹ;Egungun rẹ̀ dàbí ọ̀pá irin.
19. Òun ni olórí nínú àwọn iṣẹ́Ọlọ́run; ṣíbẹ̀ Ẹlẹ́dàá rẹ̀ fi idà rẹ̀ lé e lọ́wọ́.
20. Nítòótọ́ òkè ńláńlá ní imu ohunjíjẹ fún un wá, níbi tí gbogboẹranko ìgbẹ́ máa siré ní ẹ̀gbẹ́ ibẹ̀
21. Ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi lótósì,lábẹ́ èèsún àti ẹrẹ̀.
22. Igi lótósì síji wọn bò o;igi àrọ̀rọ̀ odò yí i kákiri.
23. Kíyèsí i, odò ńlá sàn jọjọ,òun kò sálọ; ó wà láìléwu bí óbá ṣe pé odò Jọ́rdánì ti ṣàn lọ sí ẹnu rẹ̀.
24. Ẹnìkan ha lè ímú u ní ojú rẹ̀, tàbía máa fi ọ̀kọ̀ gún imú rẹ̀?