19. Ta ni òun ti yóò bá mi ṣàròyé?Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, èmi fẹ́ pa ẹnu mí mọ́, èmi ó sì jọ́wọ́ ẹ̀mi mi lọ́wọ́.
20. “Ṣùgbọ́n, má ṣe ṣe ohun méjì yìí sí mi,Nígbà náà ni èmi kì yóò sì fi ara mi pamọ́ kúrò fún ọ:
21. Fa ọwọ́ rẹ sẹ́yìn kurò lára mi,má sì jẹ́ kí ẹ̀rù rẹ kí ó pá mi láyà.
22. Nígbà náà ni kí ìwọ kí ó pè, èmi o sì dáhùn;Ta ni jẹ́ kí ń máa sọ̀rọ̀, ki ìwọ kí ó sì dá mi lóhùn.
23. Mélòó ní àìṣedédé àti ẹ̀ṣẹ̀ mi?Mú mi mọ̀ ìrékọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ mi.
24. Nítorí kí ni ìwọ ṣe pa ojú rẹ mọ́,tí o sì yàn mí ní ọ̀tá rẹ?
25. Ìwọ ó fa ewé ya ti afẹ́fẹ́ ń fẹ́ síhìn-ín sọ́hùn-ún?Ìwọ a sì máa lépa àkémọ́lẹ̀ pòròpórò gbígbẹ?
26. Nítorí pé ìwọ kọ̀wé ohun kíkorò sí mi,o sì mú mi ní àìṣedéédéé èwe mi.
27. Ìwọ kàn àbà mọ́ mi lẹ́ṣẹ̀ pẹ̀lú,ìwọ sì ń wò ipa ọ̀nà ìrìn mi ní àwòfín;Ìwọ sì ń fi ìlà yí gìgisẹ̀ mi ká.
28. “Àní, yí ẹni tí á ti run ká, bí ohuntí ó bu, Bí aṣọ tí kòkòrò jẹ bàjẹ́.