17. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi ní ìfàyàbalẹ̀, àti àṣọpé mí ni etí yín.
18. Wò ó nísinsin yìí, èmi ti làdí ọ̀ran mi sílẹ̀;èmi mọ̀ pé a ó dá mi láre.
19. Ta ni òun ti yóò bá mi ṣàròyé?Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, èmi fẹ́ pa ẹnu mí mọ́, èmi ó sì jọ́wọ́ ẹ̀mi mi lọ́wọ́.
20. “Ṣùgbọ́n, má ṣe ṣe ohun méjì yìí sí mi,Nígbà náà ni èmi kì yóò sì fi ara mi pamọ́ kúrò fún ọ:
21. Fa ọwọ́ rẹ sẹ́yìn kurò lára mi,má sì jẹ́ kí ẹ̀rù rẹ kí ó pá mi láyà.
22. Nígbà náà ni kí ìwọ kí ó pè, èmi o sì dáhùn;Ta ni jẹ́ kí ń máa sọ̀rọ̀, ki ìwọ kí ó sì dá mi lóhùn.
23. Mélòó ní àìṣedédé àti ẹ̀ṣẹ̀ mi?Mú mi mọ̀ ìrékọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ mi.
24. Nítorí kí ni ìwọ ṣe pa ojú rẹ mọ́,tí o sì yàn mí ní ọ̀tá rẹ?