13. Nígbà náà Móábù yóò sì tú u nítorí kémósì,bí ojú ti í ti ilé Ísírẹ́lìnígbà tí ó gbẹ́kẹ̀lé Bétélì.
14. “Báwo ni o ṣe lè sọ pé, ‘ajagun ni wá,alágbára ní ogun jíjà’?
15. A ó pa Móábù run, a ó sì gba àwọn ìlú rẹ̀;a ó sì dúńbú àwọn arẹwà ọkùnrin rẹ̀,”ni Ọba wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
16. “Ìṣubú Móábù súnmọ́;ìpọ́njú yóò dé kánkán.
17. Ẹ dárò fún, gbógbó ẹ̀yin tí ó yí i kágbogbo ẹ̀yin tí ẹ mọ bí ó ti ní òkìkí tó.Ẹ sọ pé, ‘Báwo ni ọ̀pá agbára rẹtítóbi tí ó sì lógo ṣe fọ́!’
18. “Sọ̀kalẹ̀ níbi ògo rẹ,kí o sì jókòó ní ilẹ̀ gbígbẹ,ẹ̀yin olùgbé ọmọbìnrin Díbónì,nítorí tí ẹni tí ó pa Móábù runyóò dojúkọ ọ́yóò sì pa àwọn ìlú olódi rẹ run.
19. Dúró lẹ́bàá ọ̀nà kí o sì wòran,ìwọ tí ń gbé ní Áróà.Bí ọkùnrin tí ó sálọ àti obìnrin tí ó ń sá àsálà‘kí ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀?’
20. Ojú ti Móábù nítorí tí a wó o lulẹ̀,ẹ hu, sì kígbe síta!Ámónì kéde péa pa Móábù run.
21. Ìdájọ́ ti dé sí Pílátéùsórí Hólónì, Jáhásà àti Mẹ́fátì,
22. sórí Díbónì, Nébò àti Bẹti Díbílátaímù