Ní òní èmi ti sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè alágbára, òpó ìrin àti odi idẹ sí àwọn Ọba Júdà, àwọn ìjòyè rẹ̀, sí àwọn àlùfáà àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà.