Ó sì wí fún àwọn àgbààgbà pé, Ẹ dúró dè wá níhìn-ín yìí, títí àwa yóò fi tún padà tọ̀ yín wá, sì kíyèsìí, Árónì àti Húrì ń bẹ pẹ̀lú yín, bí ẹnikan bá ni ọ̀ràn kan, kí ó tọ̀ wọ́n lọ.