Nítorí náà, báyìí ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí,“Ẹ̀yin ènìyàn mi tí ó ń gbé Ṣíhónì,Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn Ásíríà,tí ó ń fi ọ̀pá lù yín,tí wọ́n sì ń gbé ọ̀gọ tìyín bíÉjíbítì ti ṣe.