Ọba sì pe àwọn ará Gíbíónì, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀; àwọn ará Gíbíónì kì í ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n wọ́n jẹ́ àwọn tí ó kù nínú àwọn ọmọ Ámórì; àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ti búra fún wọn: Ṣọ́ọ̀lù sì ń wá ọ̀nà àti pa wọ́n ní ìtara rẹ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti Júdà.