Ọba sì pàṣẹ fún Jóábù àti Ábíṣáì àti Ítaì pé, “Ẹ tọ́jú ọ̀dọ́mọkùnrin náà Ábúsálómù fún mi.” Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì gbọ́ nígbà tí ọba pàṣẹ fún gbogbo àwọn balógun nítorí Ábúsálómù.