28. Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù sì wá mọ̀ pé Olúwa wà pẹ̀lú Dáfídì tí ọmọbìnrin rẹ̀ Míkálì sì fẹ́ràn Dáfídì,
29. Ṣọ́ọ̀lù sì tún wá bẹ̀rù rẹ̀ sí, ó sì jẹ́ ọ̀ta rẹ̀ fún gbogbo ọjọ́ rẹ̀ tó kù.
30. Àwọn olórí ogun Fílístínì tún tẹ̀ṣíwájú láti lọ sí ogun, ó sì ṣe lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n lọ, Dáfídì ṣe àṣeyọrí ju gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ṣọ́ọ̀lù lọ, orúkọ rẹ̀ sì gbilẹ̀.