Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti jẹ, tí wọ́n tún mu tán ní Ṣílò, Hánà dìde wá ṣíwájú Olúwa. Nígbà náà, Élì àlùfáà wà lórí àga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu ọ̀nà ilé Olúwa ní ibi tí ó máa ń jókòó.