49. Nígbà tí Ṣáúlì sì kú, Báli-hánánì, ọmọ Ákíbórì sì jẹ ọba ní ipò Rẹ̀.
50. Nígbà tí Báli-hánánì sì kú, Hádádì sì di ọba nípò Rẹ̀. Orúkọ ìlú Rẹ̀ sì ni Páì; àti orúkọ ìyàwó sì ni Méhélábélì ọmọbìnrin Métírédì, ọmọbìnrin Mésíhábù.
51. Hádádì sì kú pẹ̀lú.Àwọn olórí Édómù ni:Tímínà, Álífà, Jététì
52. Óhólíbámà, Élà, Pínónì.
53. Kénásì, Témánì, Mísárì,
54. Mágádíẹ́lì àti Ìrámù. Àwọn wọ̀nyí ni Olórí Édómù.